HYMN 60

6.7s (FE 77)
Tune: “Apata Ayeraiye"



1.  AWA Egbe Kerubu

    Ati Serafu laiye

    Awa mbebe fun ‘ranwo

    Agbara Emi Mimo.

Egbe:  A! Baba sanu fun wa

           ko dari ese ji wa.


2.  Ki fitila Re ma ku

     Ninu Eghe Serafu

     Ki gbogbo isesi wa

     Fi wa han bi Omo Re.

Egbe:  A! Baba sanu fun wa

           ko dari ese ji wa.


3.  Mase ta wa nu kuro

     Iwo olugbala wa

     K‘awa ma ba sako Io,

     Mu wa rIn ona tire.

Egbe:  A! Baba sanu fun wa

           ko dari ese ji wa.


4.  Jehovah Jire Baba,

     Pese f'awon alaini

     At’awon ti ko ri se

     Masai ranti won loni.

Egbe:  A! Baba sanu fun wa

           ko dari ese ji wa.


5.  Ese wa ti papo ju,

     Bi yanrin eti okun

     Awa nfe ‘mularada

     lwenumo ese wa.

Egbe:  A! Baba sanu fun wa

           ko dari ese ji wa.


6.  Jehovah Emmanueli,

     Iwo ni ireti wa,

     Mase je koju ti wa

     L'ojo nla 'dajo.

Egbe:  A! Baba sanu fun wa

           ko dari ese ji wa.


7.  Odagutan Olorun

     Baba at’Emi Mimo

     We ma mo patapata,

     Ko to kuro laiye yi.

Egbe:  A! Baba sanu fun wa

           ko dari ese ji wa.  Amin

English »

Update Hymn