HYMN 599

1.  Gba t’a b’Oluwa rin 

     N’nu ‘mole Oro re

     Ona wa yoo ti ni ‘mole to 

     Gba t’a ba n se ‘fe Re 

     Oun yoo maa ba wa gbe

     Ati awon t‘o gbekele won le e 

Egbe:  Sa gekele e

           Ona miiran ko si

           Lati l'ayo n'nu Jesu

           Ju pe k'a gbeke le.


2.  Ko s‘ohun t’o le de

     L’oke tabi n‘ile

     T’o le ko agbara Re l‘oju 

     Iyemeji, eru

     Ibanuje, ekun

     Ko le duro b’a ba gbekele e. 

Egbe:  Sa gekele e...


3.  Ko si wahala mo

     Tabi ibanuje

     O ti san gbogbo ‘gbese wonyi 

     Ko si arokan mo

     Tabi ifajuro

     Sugbon ‘bukun b’a bagbekele e.

Egbe:  Sa gekele e...


4.  A ko le f’enu so

     B’ife Re ti po to

     Titi a o fi f’ara wa rubo 

     Aanu ti o n fi han 

     At’ayo t’O n fun ni
    
     Je ti awon ti o gbekele e. 

Egbe:  Sa gekele e...


5.  N’idapo pelu Re

     A o jokoo l’ese re

     Tabi ki a maa rin pelu Re 

     Awa yoo gbo ti Re 

     A o j’ise t'O ran wa

     Ma beru, sa gbekele e nikan.

Egbe:  Sa gekele e

           Ona miiran ko si

           Lati l'ayo n'nu Jesu

           Ju pe k'a gbeke le.  Amin

English »

Update Hymn