HYMN 597

(FE 623)
Tune: Eyin Omo Egbe Kerubu 



1.  JEHOVAH Rufi Baba wa 

     Fun wa l’okan okun ilera 

     Ki a le jo f’iyin fun Baba 

     Gege bi awon t’orun.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu (2) 

          Ipe na ndun, ronupiwada 

          A! e wa k'a sin Jesu.


2.  Gbogbo aiye, e yin Jesu 

     Ohun rere d’ode

      E f’iyin fun Baba l’oke 

      T’o d’Egbe yi sile.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


3.  Gbogbo onigbagbo Ijo 

     Orun ododo d’ode 

     Olorun npe nsisiyi

     E jek’a gbo ipe Re.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


4.  Jehovah Nissi Baba wa 

     Jek'a le je tire 

     Emi Mimo ‘Daba orun 

     Jowo to wa s’ona.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


5.  Ma banuje, ma b’ohun bo 

     Ninu Egbe Serafu 

     Olupese, Olugbala

     Ki yio fi o sile.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


6.  Enyin Angeli mererin 

     T’e gbe aiye dani 

     E jowo ma f'aiye sile O

     E ma wo ‘ wa eda.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


7.  Maikeli mimo pelu ida Re 

     Ngesin fo yi wa ka 

     Kerubu pelu ogun re

     La ‘ju awon ariran.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


8.  A! ojo nla, ojo dajo

     Ma jek’oju ti wa

     T’oju gbogbo aiye yio pe 

     Lodo Baba l’oke.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


9.  Jesu masai ran wa lowo 

     Mase fi wa sile

     Gbati danwo ba yi wa ka 

     Jesu gbe wa leke.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


10.  Ko s’ore t’o dabi Jesu 

       Ko s‘eni mba kepe

       Mo wo waju mo wo ehin 

       Alabaro ko si.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


11.  Ranti pe o ti ko esu 

       Ati gbogbo ise re 

       Egun ni fun o bi o tun 

       Pada sodo Esu.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


12.  Ogo ni fun Baba l’oke 

       Ogo ni f’Omo Re 

       Ogo ni fun Emi Mimo

       Metalokan lailai.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu (2) 

          Ipe na ndun, ronupiwada 

          A! e wa k'a sin Jesu.  Amin

English »

Update Hymn