HYMN 594

C.M.S 395 H.C 344 L.M (FE 620) 
"Awon oluranlawo ninu Kristi Jesu"
- Rom. 16:3



1.  KO mi, Oluwa, bi a ti

     Je gbohungbohun, oro Re 

     B’O ti wa mi, je k‘emi wa 

     Awon omo Re t’o ti nu.


2.  To mi, Oluwa, ki nle to 

     Awon asako si ona

     Bo mi, Oluwa, ki nle fi 

     Manna Re b‘awon t’ebi npa.


3.  Fun mi l’agbara, fi ese 

     Mi mule lori apata

     Ki nle na owo igbala 

     S’awon t’o nri sinu ese.


4.  Ko mi, Oluwa, ki nle fi 

     Eko rere Re k’elomi 

     F’iye f’oro mi, k’ o le fo 

     De ikoko gbogbo okan.


5.  F'isimi didun Re fun mi 

     Ki nle mo, bi i ti ye lati 

     Fi pelepele soro Re 

     Fun awon ti are ti mu.


6.  Jesu, fi ekun re kun mi 

     Fi kun mi li opolopo

     Ki ero ati oro mi

     Kun fun ife at'iyin Re.


7.  Lo mi, OLuwa, an’emi

     Bi o ti fe, nigbakugba 

     Titi em’o fi r'oju Re

     Ti ngo pin ninu ogo Re.  Amin

English »

Update Hymn