HYMN 592

H.C 352. 4s 10s (FE 618)
"Lo sise loni l’ogba ajara mi"
- Matt.21:28



1.  WA, ma sise

     Tani gbodo sole ninu oko 

     Gbati gbogbo enia nkore jo 

     'Kaluku ni Baba pase fun pe 

     “Sise Ioni"


2.  Wa, ma sise

     Gba' pe giga ti angeli ko ni 

     Mu hinrere to t‘agba t’ewe lo

     Ra gba pada, wawa l’a akoko 

     nlo Ile su tan.


3.  Wa, ma sise

     Oko po, alagbase ko si to 

     A n’ibi titun gba, a ni’po‘ro

    Ohun ona jijin, at’itosi 

    Nkigbe pe, ‘Wa.


4.  Wa ma sise

     Le ‘yemeji on aigbagbo jinna 

     Ko s'alailera ti ko le se nkan

     Ailera l’Olorun a ma lo ju 

     Fun ‘se nla Re.


5.  Wa, ma sise

     ‘Simi ko si, nigbat'ise osan 

     Titi orun yio fi wo l'ale

     Ti awa o si gbo ohun ni pe 

     O seun omo.


6.  Wa, ma sise

     Laala ni dun, ere re si daju 

     ‘Bukun f’awon t’o f’ori ti d’opin 

     Ayo won, ‘simi won, y'o ti po to 

     Lod' Oluwa!  Amin

English »

Update Hymn