HYMN 591

H.C 346 5.6s (FE 617)
"Emi o si pelu re, Emi o si ko
o li eyiti iwo o wi" - Eks.4:12



1.  TAN ‘mole Re si wa

     Loni yi Oluwa

     Fi ara Re han wa 

     N’nu oro Mimo Re 

     Jo m’okan wa gbona 

     K'a ma wo oju Re 

     K’awon ‘mode le ko 

     lyanu ore Re.


2.  Mi si wa Oluwa 

     lna Emi Mimo 

     K‘a le fi okan kan
  
     Gbe oruko Re ga 

     Jo fi eti igbo 

     At’okan ironu 

     Fun awon ti a nko 

     L’ohun nla t’O ti se.


3.  Ba ni so, Oluwa 

     Ohun to ye k’a so 

     Gege bi oro Re

     Ni ki eko wa je 

     K’awon agutan Re 

     Le ma mo ohun Re 

     lbit’ O nto won si 

     Ki nwon si le ma yo.


4.  Gbe ‘nu wa Oluwa

     K'ife Re je tiwa

     lwo nikan lao fi

     lpa wa gbogbo sin

     K’iwa wa je eko

     Fun awon omo Re

     K’o si ma kede Re

     Ninu gbogbo okan.  Amin

English »

Update Hymn