HYMN 590

C.M.S,.391 H.C 351 L.M (FE 616) 
“Bi enikan ba nfe lati ma to mi lehin, 
ki o ara re, ki o si ma gbe agbelebu 
re lojo gbogbo ki o si ma to mi lehin”
- Luku.9:23



1.  GB'AGBELEBU re ni Kristi wi 

     B'o ba fe s’omo ehin Mi

     Se ‘ra re ko aiye sile

     Si ma fi ‘rele tele mi.


2.  Gb’agbelebu re, ma je ki 

     Iwuwo re fo o laiya

     Ipa mi y‘o gb’emi re ro 

     Y‘o m’okan at’apa re le.


3.  Gb'agbelebu re ma tiju 

     Ma je k’okan were re ko 

     Oluwa ru agbelebu

     Lati gba o lowo iku.


4.  Gb’agbelebu re, ma tele

     Mase gbe sile tit'iku

     Enit' o ru agbelebu

     L’o le reti lati d’ade.


5.  'Wo Olorun Metalokan 

     L'a o ma yin titi aiye 

     Fun wa k’a le ri n’ile wa 

     Ayo orun ti ko lopin.  Amin

English »

Update Hymn