HYMN 589

C.M.S 390 H.C 349. 6.6s (FE 615)
"Nwon fi awon tikara won fun Oluwa"
- 2Kor.8:5 




1.  MO fara mi fun O

     Mo ku nitori re

     Ki nle ra o pada 

     K’o le jinde nn'oku 

     Mo f 'ara mi fun o 

     Kini ‘wo se fun Mi?


2.  Mo f’ojo aiye Mi 

     Se wahala fun o 

     Ki iwo ba le mo 

     Adun aiyeraiye

     Mo lo p'odun fun o 

     O lo kan fun Mi bi?


3.  Ile ti Baba Mi 

     At‘ite ogo Mi

     Mo fi sile w’aiye 

     Mo d' alarinkiri 

     Mo fi ‘le tori re 

     Kil’ o f'ile fun Mi?


4.  Mo jiya po fun o 

     Ti enu ko le so 

     Mo jijakadi nla 

     Tori igbala re 

     Mo jiya po fun o 

     O le jiya fun mi?


5.  Mo mu igbala nla 

     Lat’ile baba mi 

     Wa, lati fi fun o 

     Ati idariji

     Mo m’ebun wa fun o 

     Kil'o mu wa fun Mi?


6.  Fi ara re fun mi

     Fi aiye re sin Mi 

     Di ju si nkan t’aiye 

     Si wo ohun t'orun 

     Mo f‘ara Mi fun o 

     Si f'ara re fun Mi?  Amin

English »

Update Hymn