HYMN 582

ORO ALAFIA
Tune: YMHB 793 - 6s 8.4




1.  ORO Alafia

     La fi sin nyin ara 

     K’alafia bi odo nla 

     Ma ba nyin gbe.


2.  N'nu oro adura

     Af’ awon ara wa 

     Le ise Oluwa lowo 

     Ore toto.


3.  Oro ife didun 

     L'a fi p'odigbose 

     Ife wa ati t'Olorun 

     Y‘o ba won gbe.


4.  Oro'gbagbo lile

     Ni igbekele wa 

     Pe, Oluwa y’o se ranwo 

     Nigba gbogbo.


5.  Oro'reti didun 

     Y’o mu Ipinya wa dun 

     Y‘o so ayo t’o le dun ju 

     Ayo t' aiye.


6.  Odigbose, ara

     N’ife at’igbagbo

     Tit' ao fi tun pade loke 

     N'ile wa orun.  Amin

English »

Update Hymn