HYMN 580

(FE 607) 




1.  OKAN mi yo ninu Oluwa

     Tori o je lye fun mi

     Ohun re dun pupo lati gbo

     Adun ni lati r’oju Re

     Emi yo ninu Re (2ce)

     Gagbogbo l’o nfi ayo kun okan mi 

     Tori emi yo ninu Re.


2.  O ti wa mi pe ki nto mo O 

     Gbati mo rin jina sagbo

     O gbe mi wa sile l‘apa Re 

     Nibiti papa tutu wa

     Emi yo ninu Re (2ce) 

     Gbagbogbo l’o nfi ayo kun okan mi 

     Tori emi yo ninu Re.


3.  Ore at’anu Re yi mi ka 

     Or’ofe Re nsan bi odo 

     Emi Re nto, o si nse tunu 

     O ba mi lo sibikibi

     Emi yo ninu Re (2ce) 

     Gbagbogbo l’o nfi ayo kun okan mi 

     Tori emi yo ninu Re.


4.  Emi y'o dabi Re n’ijo kan

     O s’eru wuwo mi kale 

     Titi gbana ngo j’olotito
 
     K‘emi si s’oso pade Re 

     Emi yo ninu Re (2ce) 

     Gbagbogbo l’o nfi ayo kun okan mi 

     Tori emi yo ninu Re.  Amin


English »

Update Hymn