HYMN 58

S.S & 173 (FE 75)s 8s 7s
“Emi o si ba nyin da Majemu”
- Gen. 9:11



1.  OBA TI ki ye Majemu

     F'ore ofe Re fun wa,

     Majemu ti a ba O da,

     Ki awa ko le mu se.

Egbe:  Nitori iku Messaiah

           Jowo ko sanu fun wa. 2ce


2.  Oba Mimo Oba Ogo,

     Wo l‘awa nfi iyin fun

     Kerubu ati Serafu

     S'ope odun titun yi.

Egbe:  Nitori iku Messaiah...


3.  Alaileso jek'o s'eso

    Ninu odun t‘awa yi

    Alaigbagbo je ko gbagbo

    Ki gbogbo wa di yiye.

Egbe:  Nitori iku Messaiah...


4.  Oba Mimo Jehofa NLA

     Gb'ope Ajodun wa yi,

     Seri Ibukun Re sori

     Omode at‘agba wa.

Egbe:  Nitori iku Messaiah...


5.  Pese f’awon alairise,

     Pese omo fun agan

     Fi ilera fun alaisan

     K'omo Re mase rahun.

Egbe:  Nitori iku Messaiah...


6.  F'agbara Re f 'Egbe Serafu,

     Lati sin O de opin

     Mase je k‘ise wa laiye

     Ja s‘asan niwaju Re.

Egbe:  Nitori iku Messaiah...  Amin

English »

Update Hymn