HYMN 579

H.C 373 8s 7s (FE 606)
"Awon eni-irapada Oluwa yio pada, 
nwon o si wa si Sion ti awon ti 
orin” ‐ Isa.51:11



1.  NINU oru ibanuje

     L’ awon egbe ero nrin 

     Nwon nkorin reti at’ayo 

     Nwon nlo sile ileri.


2.  Niwaju wa nin'okunkun 

     Ni imole didan ntan 

     Awon arakorin nsate 

     Nwon nrin lo Ii aifoiya.


3.  Okan ni imole orun 

     Ti ntan s’ara enia Re 

     Ti nle gbogbo eru jina 

     Ti ndan yi ona wa ka.


4.  Okan ni iro ajo wa 

     Okan ni igbagbo wa 

     Okan l’eni t’a gbekele 

     Okan ni ireti wa.


5.  Okan l’orin t’egberun nko 

     Bi lati okan kan wa

     Okan n’ija okan l‘ewu 

     Okan ni irin orun.


6.  Okan ni inu didun wa 

     L’ebute ainipekun 

     Nibiti Baba wa orun 

     Y‘o ma joba titi lai.


7.  Nje k‘a ma nso arakonrin 

     T‘awa ti agbelebu

     E jek'a ru, k’a si jiya

     Tit’ ao fi ri simi.


8.  Ajinde nla fere de na

     Boji fere si sile

     Gbogbo okun y’o si tuka 

     Gbogbo lala y’o si tan.  Amin

English »

Update Hymn