HYMN 576

H.C 354 S.M (FE 603)
"E je alagbara ninu Oluwa, ati
ninu ipa agbara re" - Efesu 6:10



1.  OM-OGUN Krist, dide

     Mu hamoran nyin wo 

     Mu'pa t‘Olorun fi fun nyin 

     Nipa ti Omo re.


2.  Gbe pa Olorun wo 

     T’Oluwa om‐ogun, 

     Enit’o gbekele Jesu 

     O ju asegun lo.


3.  Ninu ipa Re nla

     On ni ki e duro

     Tori k’e ba le jija na 

     E di hamora nyin.


4.  Lo lat’ipa de ‘pa 

     Ma je ma gbadura

     Te agbara okunkun ba 

     E ja, k’e si segun.


5.  Lehin ohun gbogbo 

     Lehin gbogbo ija

     K’e le segun n'ipa Kristi 

     K‘e si duro sinsin.  Amin

English »

Update Hymn