HYMN 571

H.C 508 11s (FE 598)
"Fa mi lo si ile idurosinsin"
- Ps. 143:10



1.  DIDAN l'opagun wa

     O ntoka s‘orun

     O nfonahan ogun,

     s‘ile won orun

     Larin aginju l’a nrin,

     l’ayo l’a ngbadura

     Pel‘ okan isokan l’a ‘m' on’

     orun pon,

Egbe:  Didan I'opagun wa, 

           O ntoka s’orun

           O nfonahan ogun,

           s 'ile won orun.


2.  Jesu Oluwa wa, 

     l’ese re owo 

     Pelu okan ayo 

     l’omo Re pade

     A ti fi O sile, 

     a si ti sako,

     To wa Olugbala 

     si ona toro

Egbe:  Didan I'opagun wa...


3.  To wa l’ojo gbogbo l’ona

     t'awa nto

     Mu wa nso s’isegun 

     l'ori ota wa

     K’Angeli Re s'asa wa 

     gb’oju orun su

     Dariji, si gba wa

     l'akoko iku.

Egbe:  Didan I'opagun wa...


4.  K'a le pelu awon Angel 

     l'oke,

     Lati jumo ma yin

     n'ite ife Re

     Ghat’ ajo wa ba pin, 

     isimi y’o de

     At'alafia,

     at’orin ailopin.

Egbe:  Didan I'opagun wa, 

           O ntoka s’orun

           O nfonahan ogun,

           s 'ile won orun.  Amin

English »

Update Hymn