HYMN 569

C.M.S 371 H.C 536, 8s 6 (FE 596) 
“Tani eyi ti ngoke Iati aginju wa, ti o 
fi ara ti Olufe re?" - Orin Solo: 8:5



1.  JESU mimo, Ore airi 

     Oluranlowo alaini 

     N’nu ayida aiye, ko mi 

     K’emi le romo O.


2.  Ki nsa n’idapo mimo yi

     Gba ohun t’O fe ngo kun bi? 

     B’okan mi, b’eka ajara

     Ba sa le romo O.


3.  Are ti m‘okan mi pupo 

     Sugbon o wa r’ibi ‘simi 

     Ibukun si de s'okan mi 

     Tori t’o romo O.


4.  B'aiye d'ofo mo mi loju 

     B’a gba ore at’ara lo

     Ni suru ati laibohun 

     L’emi o romo O.


5.  Gbat’ o k’emi nikansoso

     L'arin idamu aiye yi

     Mo gb’ohun ife jeje na

     Wipe, ‘Sa romo Mi‘.


6.  B'are ba fe mu igbagbo 

     T'ireti ba si fe saki

     Ko si ewu fun okan na 

     T'o ba romo O.


7.  Ko beru irumi aiye

     Nitori ‘Wo wa nitosi
    
     Ki O si gbon b’iku ba de,

     Tori o romo O.

8.  Ire sa ni l’ohun gbogbo 

     Wo agbara at’asa mi

     Olugbala, ki y’o si nkan

     Bi mba ti romo O.  Amin

English »

Update Hymn