HYMN 565

H.C 357 11s (FE 592)
"Nitori Oluwa Olorun re, on ni 
mba o lo" - Dent.31:6



1.  E ma te siwaju, Kristian ologun, 

     Ma tejumo Jesu t'o mbe niwaju 

     Kristi Oluwa wa ni Balogun, wa 

     Wo! asia Re wa niwaju ogun.


Egbe:  E ma te siwaju, Kristian ologun 

           Sa tejumo Jesu t’o mbe niwaju.


2.  Ni oruko Jesu, ogun Esu sa 

     Nje Kristian ologun, ma nso si segun 

     Orun apadi mi ni hiho iyin 

     Ara, gbohun nyin ga,

     gb’orin nyin soke. 

Egbe:  E ma te siwaju... 


3.  Bi egbe ogun nla, n'Ijo Olorun 

     Ara, a nrin l'ona t'awon mimo rin 

     A ko ya wa n’ipa, egbe kan ni wa, 

     Okan n'ireti, l’eko okan n’ife.

Egbe:  E ma te siwaju... 


4.  Ite at’Ijoba, wonyi le parun 

     Sugbon Ijo Jesu y'o wa titi lai, 

     Orun apadi ko le bor'ljo yi

      A n’ileri Kristi, eyi ko le ye.

Egbe:  E ma te siwaju... 


5.  E ma ba ni kalo, enyin enia 

     D’ohun nyin po mo wa

     l’orin isegun 

     Ogo, iyin, ola fun Kristi Oba 

     Eyi ni y’o ma je orin wa titi.

Egbe:  E ma te siwaju, Kristian ologun 

           Sa tejumo Jesu t’o mbe niwaju.  Amin

English »

Update Hymn