HYMN 561

H.C. 363 8s 7s (FE 588)
“Apoti eri Oluwa siwaju won"
 - Num.10:33



1.  MA toju wa Baba Orun 

     Larin ‘damu aiye yi 

     Pa wa mo k‘o si ma bo wa 

     A ko n’iranwo miran 

     Sugbon gbogbo ‘bukun I'a ni 

     B’Olorun je baba wa.


2.  Olugbala, dariji wa 

     lwo sa m'ailera wa 

     Wo ti rin aiye saju wa 

     Wo ti mo ‘se inu re 

     B’en' ikanu at’alare 

     L’O ti la ‘ginju yi ja.


3.  Emi Olorun, sokale

     F’ayo orun k‘okan wa

     K’ife dapo mo iya wa 

     At’adun ti ki sun ni

     B'a ba pese fun wa bayi

     Kil' o le mi simi wa?  Amin

English »

Update Hymn