HYMN 56

1.  KRIST‘ Jesu l'agbara 
 
     Agbara 'dariji

     Agbara ti n so ni d'aaye 

     T‘o f'iye f'elese

     Krist’ Jesu l'agbara 

     Rohin re n'bi gbogbo! 

     Gbe okan ebi re to O wa 

     Yoo f’oor’ofe gba O. 

Egbe:  Krist' Jesu l'agbara 

            Agbura Olorun

            Krist' Jesu I'agbara 

            Mo jo w'okan mi fun Un 

            Krist’ Jesu l'agbara 

            Ngo gbekele E titi

            Krist' Jesu l’agbara 

            Mo ju ba, wole fun Un.


2.  Krist’ Jesu l'agbara 
 
     Lati so ni d'otun

     Lati w'ese kuro l'okan 

     Lati so di pipe

     Krist’ Jesu l’agbara 

     Lati pamo d'opin 

     Ko s’eni‘t'o le ja awon 

     Agutan low Re.

Egbe:  Krist' Jesu l'agbara...


3.  Krist‘ Jesu l‘agbara

     Lati tu ni ninu

     Agbara lati ru gbogbo 

     Aniyan okan re

     Krist’ Jesu l‘agbara

     Lati n’o’ omije nu

     Saa f‘igboya ro m’Oluwa 

     Gboran, si gbekele E. 

Egbe:  Krist' Jesu l'agbara...


4.  Krist' Jesu l’agbara 

     'Gbara lati parun 

     Lati bori ota t‘o n fe 

     Gb‘ogun ti okan re 

     Krist' Jesu l'agbara 

     Lor'akete iku

     Lati f'okan re ni ‘segun 

     Lati ji o dide 

Egbe:  Krist' Jesu l'agbara...  Amin

English »

Update Hymn