HYMN 559

C.M.S 357 H.C 356 7s.3s (FE 586) 
"E wa lairekoja, e si ma sora si i pelu
adura” - 1Pet.4:7



1.  KRISTIAN, ma ti wa ‘simi 

     Gbo b’Angeli re ti nwi

     Ni arin ota l’o wa

     Ma sora.


2.  Ogun orun-apadi

     T’a ko ri nko ra won jo 

     Nwon nso ijafara re 

     Ma sora.


3.  Wo ‘hamora ogun re 

     Wo l’osan ati l’oru 

     Esu nba, O nd‘ode re 

     Ma sora.


4.  Awon t’o segun saju 

     Nwon nwo wa b’awa ti nja 

     Nwon nfi ohun kan wipe 

     Ma sora.


5.  Gbo b’Oluwa re ti wi 

     Eniti iwo feran 

     F’oro Re si okan re 

     Ma sora.


6.  Ma sora bi enipe

     Nibe ni ‘segun re wa 

     Gbadura fun ‘ranlowo 

     Ma sora.  Amin

English »

Update Hymn