HYMN 558

H.C 295 H.C 154 t.H.C 400 
C.M (FE 585)
“Iwo ti bo aso ofo mi kuro”
 - Ps. 30:11



1.  A dupe lowo Oluwa, 

     E ki mi ku ewu 

     Fun irin ajo mi yi na 

     Ope fun Oluwa.


2.  Kerubu pelu Serafu 

     F’Ogo f’oruko Re 

     F’eni to d’Egbe yi sile 

     On li Oba Ogo.


3.  E ho, e yo, korin ogo 

     Jesu Oba ogo

     Oruko Re kari aiye 

     O mu mi lo, mo bo.


4.  Ope lo ye O, Oluwa 

     F’abo Re l’ori mi 

     Yika orile ede gbogbo 

     Ogo f’oruko Re.


5.  K’okiki Re yika aiye 

     ma bo, Oluwa mi 

     Oba Mimo, Oba aiku 

     Eni Metalokan.


6.  E korin Ologo Mimo 

     Ope ni f’Oluwa

     A lo, a bo, l’alafia 

     Mo dupe f’Oluwa.


7.  E ke Halle, Halleluyah

     F'OIorun Kerubu

     E ke Halle, Halleluyah 

     S’Olorun Serafu.  Amin

English »

Update Hymn