HYMN 557

(FE 584)
"Ilu a tedo lori oke ko Ie f’ara sin"
 - Matt.5:14



1.  AWA n’imole aiye, 

     Kerubu, Serafu

     Ilu ti a ti si oke

     Bawo ni yio ti se farasin.

Egbe:  Jek'a sise-Jek'a sise 

           Jek'a sise-Jek'a le ri

           lgbala n’ikehin.


2.  Te ‘ti lele lati gbo 

     Oro ife Jesu

     Ti o nke rara wipe

     Ha! Omo wo ha feran mi bi?

Egbe:  Jek'a sise...


3.  Kerubu on Serafu

     Lo si gbogbo agbaiye 

     Mu aiye gbo oro mi 

     Eni ba gbo y’o ri igbala.

Egbe:  Jek'a sise...


4.  Enyin ara ati ore

     E wa w’oko ‘gbala yi

     Ti Olorun gbe kale

     Ara w’oko k’ilekun to se.

Egbe:  Jek'a sise...


5.  E rantj ojo Noa

     Ti eda nse dunia

     Ti eranko fi w’oko 

     nikehin.

Egbe:  Jek'a sise...


6.  Ohun aiye mb’aiye lo

     E lo ranti aye Lot’

     Sugbon t’igbala lo ju

     Ki a mase k’abamo nikehin.

Egbe:  Jek'a sise...


7.  Baba jo ran wa lowo 

     K’a le sise re d’opin 

     Ki a gbo ohun na pe

     Kerubu, Serafu, gb’ere Re.

Egbe:  Jek'a sise-Jek'a sise 

           Jek'a sise-Jek'a le ri

           lgbala n’ikehin.  Amin

English »

Update Hymn