HYMN 555

(FE 582)
“Se giri ki o si mu aiya le” - Jos.1:9



1.  JESU ni Balogun oko 

     E mase jek’ a foiya

     Olutoko wa ni Jesu 

     E mase jek’a foiya.

Egbe:  E mase beru

           E kun fun ayo 

           Nitori Jesu I’oga oko 

           Bo ti wu ki ji na le to 

           Yio mu oko wa gunle.


2.  Enyin ero to wa l’oko

     E ke pe Jesu nikan

     K’e si gbekele nyin le pelu 

     Yio mu oko wa gunle. 

Egbe:  E mase beru...


3.  Olugbala Wo t’oro re 

     Mu igb’omi pa roro 

     Iwo t’o orin lori omi 

     T‘o sun beni ko si nkan.

Egbe:  E mase beru...


4.  Kil’ohun to mba nyin leru? 

     Enyin Omogun Kristi

     Bi Jesu ba wa ‘nu oko

     Awa yio fi ‘gbi rerin.

Egbe:  E mase beru...


5.  Gbati gbi aiye yi ba nja 

     Lor‘okun ati nile

     Abo kan mbe ti o daju 

     Lodo Olugbala wa.

Egbe:  E mase beru...


6.  Lowo Kiniun at‘ekun 

     Lowo eranko ibi 

     Jesu yio dabobo tire 

     Jesu yio pa tire mo.

Egbe:  E mase beru...


7.  Metalokan Alagbara 

     Dabobo awa omo re 

     Lowo ategun ati iji

     Jek’awa k’ alleluya. 

Egbe:  E mase beru...


8.  Ogo ni fun Baba loke 

     Ogo ni fun Omo Re 

     Ogo ni fun Emi Mimo

     Metalokan l’ope ye.

Egbe:  E mase beru

           E kun fun ayo 

           Nitori Jesu I’oga oko 

           Bo ti wu ki ji na le to 

           Yio mu oko wa gunle.  Amin

English »

Update Hymn