HYMN 55

H.C. 305, 11s (FE 72)
"K O n dide fun iranlowo mi" - Ps. 35:2



1.  OLORUN Eleda/jowo sunmo wa, 

     Awa omo Re de/lati juba Re, 

     Ran Serafu t'orun/ati Kerubu; 

     Lati wa ba wa pe/Iati jo yin O.


2.  Baba Olubukun/bukun wa loni

     Je k'ipade oni/le mu eso wa,

     Je ki omo 'mole/to wa l'okunkun 

     Wa sinu imole/lati ri ‘gbala.


3.  Tikala Re wasu/fun agutan Re,

     Maje ki nwon segbe, pe won sodo Re, 

     Maje k‘ina Re ku/ n‘ile Yoruba 

     Jeki ina Re ma/tan nibe titi.


4.  Awon ti 'Wo ti pe/ni ilu Eko

     Ati gbogbo aiye/ma fi won sile, 

    Oko ‘gbala kehin/to tun gbe kale 

    Maje k'eranko wo/l‘akoko ti wa.


5.  Enyin Egbe Seraf'/ati Kerubu 

     E ma je ko re nyin, e mase sole 

     Gbe ‘da 'segun soke, Jesu ti segun;

     Nipa agbara Re/ awa yio segun.


6.  Sugbon k'a s‘otito/ni ilana Re, 

     Yio si gbe wa nija, yio duro ti wa,

     K‘a fara da iya, ka te siwaju

     On to gbo t'Abraham/yio si gbo ti wa.


7.  Jesu Olugbala/Ore Elese

     Je ka se ife Re/ka te s'ona Re, 

     Je ka fi iwa wa/p’elomiran wa, 

     Ko si fun wa n'ife/larin ara wa.


8.  A mbe O, Eleda, Olorun tiwa 

     Fun awon ariran/ninu Egbe yi, 

     F‘iran didan han won, si tun yan 

     kun won,

     Mase jeki esu/f'iran re han won.


9.  Nigbat’o ba si di/ojo ikehin

     T‘oju gbogbo aiye, yio pe sodo Re, 

     Maje k'oju ti wa, ma je ka sokun, 

     Jek’awa Serafu/ke Halleluya. Amin

English »

Update Hymn