HYMN 546

C.M.S 432 H.C 434 t.A. & M.323 
C.M (FE 572)
“E ma se eyi ni iranti Mi"
 - Luku.22:19


1.  GEGE bi oro ore Re 

     Ninu irele nla

     Emi o s'eyi, Oluwa 

     Emi o ranti re.


2.  Ara Re ti a bu fun mi 

     Yio je onje mi

     Mo gba ago majemu Re 

     Lati se ranti re.


3.  Mo le gbagbe Gestsemane 

     Ti mo r’ijanu Re 

     Iya on ogun eje Re

     Ki nma si ranti re.


4.  Ngo ranti gbogbo rora Re 

     Ati ‘fe Re si mi

     Bi o ku emi kan fun mi 

     Emi o ranti Re.


5.  Gbati enu mi ba pamo 

     Ti iye mi ba ra

     Ti O ba de n'ljoba Re 

     Jesu, jo ranti mi.  Amin

English »

Update Hymn