HYMN 545

C.M.S 123 t.S 154. 8.7 (FE 571)
“Emi mo pe, ninu mi ko, si nkan
to dara" - Rom. 7:18



1.  BABA orun! emi fe wa 

     N’iwa mimo l'ododo 

     Sugbon ife eran-ara 

     Ntan mi je nigba gbogbo.


2.  Alailera ni emi se

     Emi mi at’ara mi

     Ese gbagbogbo ti mo nda 

     Wo mi l'orun bi eru nla.


3.  Ofin kan mbe li okan mi 

     ‘Wo papa l'o fi sibe 

     Tori eyi ni mo fi fe 

     Tele'fe at'ase Re.


4.  Sibe, bi mo fe se rere 

     Lojukanna, mo sina 

     Rere l’oro Re ma so 

     Buburu l'emi si use.


5.  Nigba pupo ni mo njowo 

     Ara mi fun idanwo

     Bi atile nkilo fun mi 

     Lati gafara f’ese.


6.  Baba orun, lwo nikan 

     L'o to lati gba mi la 

     Olugbala ti o ti ran

     On na ni ngo gba mora.


7.  Fi Emi Mimo Re to mi 
 
     S’ona titun ti mba gba 

     Ko mi, so mi, k’O si to mi 

     Iwo Emi Olorun.  Amin

English »

Update Hymn