HYMN 544

H.C 404 8s 7s (FE 570)
‘O si wi fun won pe, E ma to mi Iehin"
- Matt. 4:19-20




1.  JESU npe wa, losan loru 

     Latin irumi aiye 

     Lojojumo l‘a ngbohun Re 

     Wipe, ‘Kristian, tele Mi‘.


2.  Awon Aposteli gbani

     Ni odi Galili ni 

     Nwon ko ile, ona sile 

     Gbogbo nwon si nto lehin.


3.  Jesu npe we, kuro ninu 

     Ohun aiye asan yi

     L’arin afe aiye, O nwi 

     Pe, “Kristian e feran Mi".


4.  Larin ayo at'ekun wa 

     Larin lala on ‘rorun

     Tantan l'o npe l'ohun rara 

     Pe, “Kristian e feran Mi".


5.  Olugbala nip'anu Re 

     Jeki a gbo ipe Re

     F'eti ‘gboran fun gbogbo wa, 

     K'a fe O ju aiye Io.  Amin

English »

Update Hymn