HYMN 541

H.C 417 t.H.C 120 D. 8s.7s (FE 567)
“Ohunkohun ti o jasi ere fun mi awon 
ni mo ka s'ofo nitori Kristi” - Filip. 3:7



1.  JESU mo gb’agbelebu mi,

     Ki nle ma to O lehin

     Otosi at'eni egan

     Wo l’ohun gbogbo fun mi 

    Bi ini mi gbogbo segbe 

    Ti ero mi gbogbo pin 

    Sibe oloro ni mo je!

    Temi ni Krisit' at’Orun.


2.  Eda le ma wahala mi

     Y'o mu mi sunmo O ni 

    ldanwo aiye le ba mi 

    Orun o mu ‘simi wa 

    lbanuje ko le se nkan 

    B'ife R eba wa fun mi 

    Ayo ko si le dun mo mi 

    B’Iwo ko si ninu re.


3.  Okan mi, gba igbala re 

     Bori ese at’eru 

     F'ayo a wa ni ipokipo 

     Ma sise, si ma jiya 

     Ro t’Emi t’o wa ninu re? 

     At'ife Baba si O 

     W’Olugbala t'o ku fun o 

     Omo orun, ma se kun!


4.  Nje koja lat'ore s’ogo 

     N'n'adura on igbagbo 

     Ojo ailopin wa fun O 

     Baba y‘o mu o de be

     lse re l'aiye fere pin

     Ojo ajo re mbuse

     lreti y'o pada s'ayo 

     Adura s‘orin iyin.  Amin

English »

Update Hymn