HYMN 539

t.H.C 154 C.M (FE 565)
"Awon ti o ti gba opolopo ore-ofe ati 
ebun ododo, yio joba ninu iye nipa 
enikan Jesu Kristi" - Rom.5:17
Tune: Amazing Grace.



1.  OORE-OFE-B’ o ti dun to 

     To gba em‘ abosi

     Mo ti sonu, o wa mi ri 

     O si si mi loju.


2.  Or’ofe ko mi ki ‘m‘ beru 

     O si l’eru mi lo 

     B’ore-ofe na ti han to 

     Nigba mo ko gbagbo!


3.  Opo ewu at’idekun

     Ni mo ti la koja

     Or’ofe npa mi mo d‘oni 

     Y’o si sin mi de’le.


4.  Nje gbat' ara at‘okan ye 

     Ti emi ba si pin

     Ngo gb’ayo at’alafia 

     Loke orun lohun.  Amin

English »

Update Hymn