HYMN 536

t.H.C 18 C.M. (FE 562)
"Kiyesi o ti dara o si ti dun“ - Ps.113:1



1.  WO! b’o ti dun to lati ri 

     Awon ara at'ore

     Ara ti okan won s’okan 

     L’egbe ide mimo.


2.  Gba isan ‘fe t'odo Krist sun

     O san s'okan gbogbo 	

     Alafia Olodumare

     Dabobo gbogbo re.


3.  O dabi ororo didun

     Ni irugbon Aaron

     Kikan re m'aso re run ‘re 

     O san s’agbada re.


4.  O dara b‘iri owuro

     To nse soke Sion

     Nibit Olorun f‘ogo han 

     T'o m’ore-ofe han.  Amin

English »

Update Hymn