HYMN 534

(FE 560)
"E duro ninu ife Mi" - John15:9



1.  KERUBU ati Serafu 

     E feran ara nyin 

     Gege bi awon ti orun 

     Ti feran ara won.

Egbe:  K‘a gbekele Jesu Kristi 

           Oluwa Mima ni

           Bi mo ti ni ife Jesus 

           Emi ko le segbe.


2.  Ota po fun wa li laiye 

     Ko si alabaro

     Jesu l’Olubanidaro 

     On na lo le gba wa 

Egbe:  K‘a gbekele Jesu...


3.  Esu ti korira wa 

     O fe mu wa dani 

     Sugbon ewo la o se 

     Jesu ti pelu wa.

Egbe:  K‘a gbekele Jesu...


4.  Jesu ti segun esu 

     L’or’oke Kalfari 

     Oluwa segun fun wa 

     Ka le bori ota wa. 

Egbe:  K‘a gbekele Jesu...


5.  Olorun Orimolade 

     Jowo sanu fun wa 

     K‘O gba wa low‘ota wa 

     Ni ona wa gbogbo.

Egbe:  K‘a gbekele Jesu...


6.  Li akoko iku wa

     Mu ki okan wa mo 

     Ka ba le lo ri Jesu 

     Lodo Baba loke.

Egbe:  K‘a gbekele Jesu...


7.  A ki Baba Aladura 

     Ti baba gbe dide

     Ki Jesu ko ran lowo 

     Ko gbe owo re soke.

Egbe:  K‘a gbekele Jesu...


8.  Jehovah Rufi, Baba 

     Gb'adura ljo yi 

     Jehovah Jire Mimo 

     K’O mese wa duro.

Egbe:  K‘a gbekele Jesu...


9.  Enyin egbe Aladura 

     E mura si ise nyin 

     K’e n‘ife si ara nyin 

     Baba yio gbo ti nyin.

Egbe:  K‘a gbekele Jesu...


10.  A f’ogo fun Baba loke 

       A f'ogo f'Omo Re

       A f’ogo F'Emi Mimo

       Metalokan lailai.

Egbe:  K‘a gbekele Jesu Kristi 

           Oluwa Mima ni

           Bi mo ti ni ife Jesus 

           Emi ko le segbe.  Amen

English »

Update Hymn