HYMN 53

(FE 70)
“E fi iberu sin Oluwa" - Ps. 2:11



1.  ‘K’E wole f'Oba Ologo 

     Eni O ngbe ‘nu imole 

     T’oju elese kan ko ri 

     Dariji, Dariji.


2.  Gbogbo omo Egbe Serafu, 

     L'okunrin at’obinrin 

     K'a ronu ese ti a da,

     K'a toro 'dariji.


3.  B‘a ba mo'ra wa l'elese, 

     K'a jewo re la je tan,

     K'a ronu k’a si pawada, 

     Baba yio dariji.


4.  Ese aini ‘fe l'o poju 

     Larin wa ba ti kunle

     Esu l‘o ngb' ogun re ti wa 

     Baba jo dariji.


5.  Ninu ‘wa wa ati ‘se wa, 

     Ninu oro enu wa,

     “Nu gigan enikeji wa 

     Dariji, Daniji.


6.  Gbogbo wa Iati f‘oju ri, 

     ‘Wo lo ran ‘mole si wa, 

     Lati fi ona Re han wa 

     Dariji, Daniji.


7.  Bi ko ba se anu Re ni 

     Ka to de ‘nu ‘mole yi 

     Esu ba l’ayo lori wa 

     Dariji, Dariji.


8.  Bi ko ba s'esu t'o ngb’ogun 

     A le f‘ibi s'olore,

    Jowo pa ise esu run

    Dariji, Daniji.


9.  Wo ti 'ya ti Jesu wa je 

     ‘Ranti ogun eje Re, 

     Nin'ogba Gestesmani 

     Dariji, Dariji.


10.  A dupe p‘O ti gbo tiwa 

       Ma je k'a tun d’ese mo,

       Tun wa yipada Oiuwa,

       K’a l‘ayo l'ojo ‘kehin.  Amin

English »

Update Hymn