HYMN 529

O.t.H.C 483 C.M (FE 554) 
"E ma fi rere fe ara nyin"
 - Rom.12:10



1.  ALAFlA ni f'okan na 

     Nibiti fe gbe wa 

     Kerubu pelu Serafu

     E feran ara yin.


2.  Gegebi Kerubu orun

     Pelu Seruf‘ orun

     Awon ni nwon yi ‘te na ka 

    Nwon nyin Baba logo.


3.  Asan ni gbogbo ‘gbagbo je 

    Bi ko si ‘fe nibe

    Ese yio joba lokan wa 

    B‘ife ko si nibe.


4.  lfe nikan ni yio r‘opin

     E feran ara nyin

     Ma banuje, ma b’ohun bo 

     Ade yio je tiwa.


5.  Sugbon ife ni nwi bayi 

     E feran ara nyin

     Nipa ife a o ri Baba 

     L'oke orun lohun.


6.  Jesu Olugbala, owon 

     Fun Kerubu n’ife

     Gege bi Kerubu orun 

     Pelu Seraf' orun.


7.  Jehovah Nissi Baba wa 

     Pe wa n'Tire l‘oke 

     Emi Mimo ‘daba orun 

     Jowo f‘ona han ni.


8.  Jehovah-Rufi Baba wa

     Fun wa l’okun ‘lera

     Ka le jo fi ‘yin fun Baba 

     Gege b’awon t’orun.  Amin

English »

Update Hymn