HYMN 522

H.C 314 6 8s (FE 547)
“E duro ninu ife mi"- Joh.15:9



1.  JESU Oluwa, Oba mi 

     Gbohun mi nigbati mo npe, 

     Gbohun mi lati ‘bugbe Re, 

     Rojo ore-ofe sile.

Egbe:  Oluwa mi, mo feran Re 

           Jeki nle ma feran Re si.


2.  Jesu mo ti jafara ju 

     Ngo se le fe O, b’o ti ye 

     Em’ o se le gb’ogo Re ga 

     Ati ewa oruko Re.

Egbe:  Oluwa mi...


3.  Jesu, kil’o ri ninu mi 

     Ti ‘fe na fi po to bayi

     Ore Re si mi ti po to! 

     O ta gbogbo ero mi yo! 

Egbe:  Oluwa mi...


4.  Jesu, ‘Wo o je orin mi

     Tire l’aiye at’okan mi

     Tire ni gbogbo ini mi 

     Olugbala, Wo ni temi.

Egbe:  Oluwa mi, mo feran Re 

           Jeki nle ma feran Re si.  Amin

English »

Update Hymn