HYMN 520

O t.H.C. 53 I.M (FE 545)
"Awafe enitori onMefe wa" - I John 4:19



1.  AWA ko orin ife Re 

    Obangiji Oba Ogo

     Ko s’ohun ti lalasi Re 

     Ola Re ko si nipekun.


2.  N'nu ife l'o s’eda aiye 

     O da enia sinu re

     Lati ma s’akoso gbogbo 

     E korin ‘fe Eleda wa.


3.  Lojojumo l’ O ntoju wa

     O si mbo, O si nsike wa 

     Beni ko gba nkan lowo wa 

     Korin ‘yin s’onibu ore.


4.  O ri wa ninu okunkun 

     Pe, a o mo ojubo Re 

     N'ife O fi ona han wa 

     E korin ife Olore!


5.  N’ife O fi Jesu fun wa 

     Omo bibi Re kansoso 

     O wa ra wa lowo ese 

     A yin fe Re Olugbala!


6.  lfe Re ran oro Re wa 

     lfe Re l'o si wa leti 

     lfe Re si mu wa duro 

     E korin ore-ofe Re.


7.  Gbogbo eda kun fun ‘fe Re 

     Oluwa wa, Oba aiye 

     Gbogbo agbaiye, e gberin 

     Orin ife Olorun wa.  Amin

English »

Update Hymn