HYMN 519

H.C 327 D.C.M (FE 544)
“A dari ese re ti o po ji i, nitori
o ni ife pupo” - Luku 7:47 



1.  JESU, Oluwa, a fe O,

     Tori gbogbo ebun

     Nt'owo re da lat' oke wa

     B'iri si gbogbo aiye

     A yin O nitori wonyi

     Ki ise fun won nikan

     Ni awon omo-odo Re 

     Se ngbadura si O.


2.  Awa fe O, Olugbala 

     Tori 'gba t’a sako 

     lwo pe okan wa pada 

     Lati t' ona iye,

     Gba t’a wa ninu okunkun 

     T’a rin ninu ese

     Wo ran imole Re si wa 

     Lati f'ona han wa.


3.  Baba orun, awa fe O,

     Nitori Wo fe wa 

     Wo ran Omo Re lati ku

     Ki awa le n’iye

     Gbat’ a wa labe ‘binu Re 

     Wo fun wa n’ireti

     Bi ese t‘a da ti po to 

     Be l‘ o dariji wa.  Amin

English »

Update Hymn