HYMN 518

C.M.S 334 H.C 320 C.M (FE 543)
"Oruko Jesu Omo Mimo Re” lse. 4:30




1.  ORUKO kan mbe ti mo fe 

     Mo fe ma korin re 

    Iro didun ni l’eti mi 

    Oruko didun ni.


2.  O so ife Olugbala 

     T’o ku lati ra mi

     O so t’eje re ‘yebiye 

     Etutu f’elese.


3.  O so ti iyonu baba 

     T'O ni si Omo Re

     O m’ara mi ya, lati la 

     Aginju aiye ja.


4.  Jesu, Oruko ti mo fe

     T‘o si dun l’eti mi,

     Ko‘ s’eni mimo kan l’aiye 

     T‘o mo b’o ti po to.


5.  Oruko yi j’orun didun 

     L'ona egun t’a nrin 

     Yio tun ona yangi se 

     T'o lo s’odo Olorun.


6.  Nibe pelu awon mimo 

     Ti nwon ‘bo nin’ese? 

     Emi o korin titun ni 

     T’ife Jesu si mi.  Amin

English »

Update Hymn