HYMN 514

H.C 315 C.M (FE 539) 
"Ki Kristi le ma gbe okan nyin 
nipa igbagbo” - Efe 3:17



1.  JESU, kiki ironu Re

     Fi ayo kun okan 

     Sugbon k’a ri O lo dun ju 

     K'a simi lodo Re.


2.  Enu ko so, eti ko gbo
   
     Ko ti okan wa ri

     Or’ko, t’o sowon, t‘o dun bi 

     Ti Jesu Oluwa.


3.  Ireti okan ti nkanu 

     Olore elese

     O seun f’awon ti nwa O 

     Awon t’o ri O yo.


4.  Ayo won, enu ko le so 

    Eda ko le rohin 

    Ife Jesu, b’o'ti po to 

    Awon Tire l'o mo.


5.  Jesu, Wo ma je ayo wa 

     Wo sa ni ere wa

     Ma je ogo wa nisiyi 

     Ati titi lailai.  Amin

English »

Update Hymn