HYMN 511

1.  AH! ojo iyanu ojo ’yanu

     Ojo ti n ko le gbagbe

     Gba mo sako lo ninu okunkun 

     Ni mo ba Jesu pade

     Ore olufe, Eni ikaanu

     B'okan aini mi pade

     O mu beru lo, pel'ayo ni mo n rohin 

     O mu ghogb' okunkun lo! 

Egbe:  Ogo orun si kun ‘nu okan mi

           Gba t’Olugbala so mi di pipe 

           A we ese mi nu, ale mi si d'owuro 

          Ogo orun si kun 'nu okan mi.


2.  A bi mi nipa Emi pelu ye 

     Sinu ebi Olorun

     A da mi lare nipa 'fe Kristi 

     Mo ni‘gbekele t’o ga

     Ise naa di sise logan nigba

     Ti mo wa bi elese

     Mo gba ebun oor-ofe eyi t’O mu wa

     O gba mi, yin Ooko Re.

Egbe:  Ogo orun si kun ‘nu...


3.  Nisin yi mo n’ireti t’o wa lae 

     Lehin opin ajo mi

     O daju pe mo n’ireti l’orun 

     N’ile ologo julo

     Ati nitori ojo yanu ni

     Ti mo wole l'ese Re

    Oro ainipekun ibukun l’atorun 

    Ti mo gba ni owo Re.

Egbe:  Ogo orun si kun ‘nu okan mi

           Gba t’Olugbala so mi di pipe 

           A we ese mi nu, ale mi si d'owuro 

          Ogo orun si kun 'nu okan mi.  Amin

English »

Update Hymn