HYMN 509

H.C. 4366 8s. 7s (FE 537)
“Oluwa yio ja fun nyin" - Eks.14:14



1.  OM'OGBE Kerubu jade 

     Gbogbo aje pagan mo 

     Awa Serafu l'o pejo 

     Lati gb’ogo Jesu ga. 

Egbe:  Maikeli Mimo

           Ni Balogun Egbe wa.

           Maikeli Mimo

           Ni Balogun Egbe wa.


2.  Aje ko Ie ri wa gbese 

     Labe opagun Jesu 

     Niwaju awon Serafu 

     Gbogbo aje a fo lo.

Egbe:  Maikeli Mimo...


3.  Idarudapo yio b’aje 

     Niwaju ogun Jesu 

     ldaj’Olorun de be won 

     Lagbara Metalokan. 

Egbe:  Maikeli Mimo...


4.  Halleluya! Halleluya! 

     Jek’a ko Halleluyah 

     Ajekaje ko lagbara 

     Lori Egbe Kerubu. 

Egbe:  Maikeli Mimo...


5.  Gidigbo, gidigbo heyah 

     A p'awon aje n'ija

     Ati soponna baba won 

     Loruko Metalokan. 

Egbe:  Maikeli Mimo...


6.  E f'ogo fun baba loke

     E f’ogo fun Omo Re 

     E.f’ogo fun Emi Mimo

     F’ ogo fun Metalokan.

Egbe:  Maikeli Mimo

           Ni Balogun Egbe wa.

           Maikeli Mimo

           Ni Balogun Egbe wa.  Amin

English »

Update Hymn