HYMN 508

(FE 536)
"Olorun igbala wa" - Ps. 65:5


1.  OLORUN t’o gbo ti Dafidi
 
     Lori awon Ota re 

     Olorun to gbo ti Esther 

     T’o si segun Hamani. 

Egbe:  Gb’adura wa, Oba olore 

           Gege bi a ti nke pe O 

           Mase je k’omo Re rahun 

           L'a tunbotan aiye wa.


2.  Hosanna Oba Ologo 

     Kabiyesi f ’Oba wa, 

     F’ebun ore-ofe Re fun wa 

     K’awa le sin O d’opin. 

Egbe:  Gb’adura wa...


3.  Olorun to gbo ti Hanna 

     Jowo gbo t’awon agan wa 

     Olorun to gbo ti Serah 

     Sanu f’awa omo Re.

Egbe:  Gb’adura wa...


4.  Awa Omo Egbe Serafu 

     Ti aginju aiye yi

     F'ebun Emi Mimo Re fun wa,

     K‘a wa le jere ade.

Egbe:  Gb’adura wa...


5.  Olorun to gbo Elija 

     Leba odo Jodan 

     Olorun to gbo ti Mose 

     Lori oke Sinai. 

Egbe:  Gb’adura wa...


6.  B'o ti wu k' orun ko mu to 

     Sanma dudu die yio wa 

     B'o ti wu k'aiye wa l'ayo 

     Yo n’ akoko ekun re. 

Egbe:  Gb’adura wa...


7.  L’ohun kan gbogbo wa kunle 

     Pa ese run l'okan wa

     F’ebun meje orun Re fun wa, 

     Ki ‘fe wa le ma po si.

Egbe:  Gb’adura wa, Oba olore 

           Gege bi a ti nke pe O 

           Mase je k’omo Re rahun 

           L'a tunbotan aiye wa.  Amin

English »

Update Hymn