HYMN 506

H.C 123, 579 10s 11s (FE 534)
"Nwon ko si simi losan ati laju, wipe,
Mino, Mimo, Mimo" - Ifihan.4:8
Tune: Aigbagbo bila temi l’Oluwa




1.  KERUBU e yo, Serafu e yo 

     F‘egbe Mimo yi ti Baba fun wa

     T'o ju ogbon ati ero eda lo 

     Ogo, lyin, Ola fun Metalokan.


2.  Eda ko nipa lori Egbe yi 

     Sa ma se rere iwo yio segun

     Ma si se fi Eda se ‘gbekele Re 

     OIorun Eleda ko ni gbagbe Re.


3.  Aje ko n’ipa lori Egbe yi 

     Oso ko n‘ipa lori Egbe yi

     Sa te le ona t’Oluwa la sile 

     lsegun y‘o je tire lona gbogbo.


4.  Kerubu nkigbe, Eda ko mira 

     Serafu nkigbe, Eda ko bere

     Awawi ko ni si fun nyin lojo na 

     T’eda t'Angeli yio pelu dandan.


5.  Olodumare gbo adura mi 

     Ki nle tele O d’opin aiye mi

     Ki oju ma ti mi ni opin aiye mi 

     Ki ngbo, o se omo, bo si aye re.


6.  Ghana la o ko ‘rin Halleluya 

     Ni’waju ite Olodumare 

     T‘Olugbala y’o tan mole Re si wa 

     K‘ori awa mase ko ‘ye ainipekun.


7.  Ogo fun Baba, Ogo fun Omo 

     Ogo f’Emi Mimo, Metalokan 

     B’ero eda ko tile mo ‘jinle Re 

     A o ma yin O sibe titi aiye.  Amin

English »

Update Hymn