HYMN 505

(FE 533)
Ohun Orin: Ru iti wole



1.  GBOGBO Egbe Seraf to wa ni

     gbogb‘aiye

     E sin Olugbala l'emi at‘oto 

     E fi keta sile, e feran ara nyin 

     Gbogbo wa ni Jesu

     Olugbala npe.

Egbe:  Wa k'a jumo rin, wa k'a jumo rin 

           Wa si Egbe Seraf ati kerubu 

           Wa k'a jumo rin, wa

           k'a jumo rin

           Wa si Egbe Seraf' wa gb’emi re Ia.


2.  Nigbat‘ aiye ti se ti awa ti d‘aiye 

     A gbo wipe Jesu lo segun Esu 

     Awa Egbe Seraf’ y‘o si segun Esu 

     Li Oruko Olorun Metalokan.

Egbe:  Wa k'a jumo rin...


3.  Awa Aje, Oso, ko ni agbara kan 

     Lori Egbe Seraf‘ati Kerubu 

     Egbe aladura, e damure giri

     K’a le segun Esu pelu ogun re. 

Egbe:  Wa k'a jumo rin...


4.  Enyin Egbe Akorin,

     E tun ohun nyin se

     Lati yin Olugbala wa li ogo 

     Gbogb‘awon t'o ti ja

     nwon si segun esu

     Mura k‘enyin na le segun bi ti won, 

Egbe:  Wa k'a jumo rin...


5.  Aiye le ma kegan, nwon si

     le ma sata,

     Sugbon Serafu mo Ent‘on nsin 

     lwo m’Eniti o nsin,

     Enit’ o nsin mo o

     Sa tejumo Jesu, iwo yio segun. 

Egbe:  Wa k'a jumo rin...


6.  Nigbat‘a ba pari ise wa ni aiye

     A o gb’ade lehin irin ajo wa

     Jesu Olugbala, yio ko wa de kenian 

     Ile ileri na ti Oga Ogo.

Egbe:  Wa k'a jumo rin, wa k'a jumo rin 

           Wa si Egbe Seraf ati kerubu 

           Wa k'a jumo rin, wa

           k'a jumo rin

           Wa si Egbe Seraf' wa gb’emi re Ia.  Amin

English »

Update Hymn