HYMN 504

PM S.S. (FE 532)
"Ajagun Oba" - 2Tim. 2:3




1.  AWA omo ogun Oba ti a f’eje Re ra

     A si mura lati jagun fun Kristi Oluwa 

     A ngb’arin ota wa, sugbon

     a nf'ayo korin

     Okan wa yio duro gbonyin-gbonyin.

Egbe:  Awa omo ogun Oba 

           A o korin iyin Re

           A o si ja tokan‐tokan 

           F'Oba Ologo julo.


2.  Aw’omo ogun Oba, a o f‘ayo j'oko Re 

     O ko eniti a kan mo ‘gi

     gba Kristi Oba wa mbe

     Adanu l'ere aiye ao f'ayo gba iya

     lati bowo f’oruko Re, b‘ omo ogun Oba.

Egbe:  Awa omo ogun Oba...


3.  Awa omo ogun Oba, ao jade pelu Re 

     Bi awa ba le jiya, k’a si ru itiju

     K‘a gb’asia Re ga, ‘tori akoko nlo

     A ti gba ade nsunmole

     f‘awon omo ogun Oba.

Egbe:  Awa omo ogun Oba 

           A o korin iyin Re

           A o si ja tokan‐tokan 

           F'Oba Ologo julo.  Amin

English »

Update Hymn