HYMN 503

8.7.8.7.D.
“Ore mi li eyin ise" - Jn 15:14




1.  ORE wo l’a ni bi Jesu

     Ti O ru ‘banuje wa 

     Anfaani wo I’o po bayi 

     Lati maa gbadura si I 

     Alaafia pupo l’a n sonu 

     Iror’ainidi l’a n je

     ‘Tori a ko n fi gbogbo nnkan 

     S’adura niwaju Re.


2.  Idanwo ha wa fun wa bi? 

     A ha ni wahala bi

     A ko gbodo so ‘reti nu 

     Sa gbadura s‘Oluwa,

     A'a le ri ore olooto 

     Ti o Ie ba wa daro 

     Jesu ti mo ailera wa, 

     Sa gbadura s'Oluwa.


3.  Eru han won wa l'orun bi? 

     Aniyan ha po fun wa? 

     Olugbala ni aabo wa,

     Sa gbadura s‘Oluwa 

     Awon ore ha sa o ti?

     Sa gbadura s’Oluwa

     Yoo gbe o soke l’apa Re, 

     lwo yoo si n'itunu.  Amin

English »

Update Hymn