HYMN 502

Tune: Will your Anchor Holds?



1.  IWO ha ni idakoro t’o daju 

     Ninu irumi at’iji aye 

     Nigba ti ikun omi ba dide 

     Idakoro re ha le duro.

Egbe:  ldakoro n be fun okan wa 

           B’o ti wu ki iji naa le to

           Jesu l’Apata ti ko le ye 

           Lor’Apata ife Re l'a n duro.


2.  A ti gunle s’ebute isinmi

     Ko s’ewu a n be lowo Oluwa 

     Dakoro t’O ti s’inu okan mi 

     Yoo duro b’o ti wu k’iji le to.

Egbe:  ldakoro n be fun okan wa...


3.  Yoo duro sinsin b’eru tile de

     Awon ota wa ni oju yoo ti 

     Ko si igbi t‘o le ba wa l’eru 

     Awa n'idakoro t'o daju. 

Egbe:  ldakoro n be fun okan wa...


4.  Yoo duro girl titi de opin 

     Titi iku yoo ti p’oju wa de 

     Looro ajinde ko si Ie kuna 

     Oun n‘idakoro ireti wa.

Egbe:  ldakoro n be fun okan wa...


5.  ‘Gba t'oju wa ba r'ewa ogo Re 

     Ni ebute ti a fi wura ko

     A o duro lor'idakoro wa 

     Gbogbo iji yoo re wa koja.

Egbe:  ldakoro n be fun okan wa 

           B’o ti wu ki iji naa le to

           Jesu l’Apata ti ko le ye 

           Lor’Apata ife Re l'a n duro.  Amin

English »

Update Hymn