HYMN 501

(FE 529) 
Tune: Oluwa Olorun gba wa
“E ma foiya awon eniti npa ara"
- Matt. 10:28



1.  OLORUN wa, awa mbe O 

     Sokale si arin wa

     Ran agbara ‘segun nla Re 

     S‘ori awon omo Re 

     F'ore ofe igbala

     Yi awa omo Re ka

     K‘a le ma yo n'nu ore Re

     K’a si le segun ota. 

Egbe:  O d'ofo (4)
   
            Ajahula Sakula 

            Agbara aje d'ofo.


2.  Enyin Angeli Olusegun 

     Sokale l’agbara Re

     E dide pel’ohun ija yin 

     Lati segun f’Egbe yi 

     Emi-Mimo daba orun 

     Fi ore isegun Re

     Yi awa omo Re ka

     K‘a le ma yo ‘nu segun. 

Egbe:  O d'ofo...


3.  Karubu oni ‘da ina 

     Sokale l'agbara Re 

     Maikel olori ogun wa 

     Sokale l‘agbara Re 

     Awa omo Re duro

     De agbara ina na

     T'o sakale sara won

     T‘o sote s'awon omo Re.

Egbe:  O d'ofo...


4.  Olorun Alagbara nla

     T‘o pa ara Egypt run

     T’o ri won sinu okun pupa 

     Ti nwon ko le dide mo 

     Sokale Eleda wa

     Doju ota wa bo le

     Ki nwon subu n’iwaju Re 

     Ki nwon si di ‘temole.

Egbe:  O d'ofo...


5.  E ma yo enyin enia mi 

     Ninu agbara nla mi

     E ho iho isegun nla

     Bi t’ awon omo Isreal 

     Maikel ti segun fun nyin 

     O si di nyin l’amure

     Te siwaju n’ipa agbara Re, 

     E ja k’e si le segun.

Egbe:  O d'ofo...


6.  Emi ni El El-Sahula 

     Oba Ajasegun ni mi 

     Emi ni Jehofa Hullam 

     Oba Awimayehun

     E ma yo ninu ore mi 

     K’e si ma dupe pelu 

     Emi ni Asaholah

     Oba a-fi-dip’o-te‐mole.

Egbe:  O d'ofo (4)
   
            Ajahula Sakula 

            Agbara aje d'ofo.  Amin

English »

Update Hymn