HYMN 500

(FE 528) PM
“Nwon si fori bale fun Olorun ti o
joko lori ite,  wipe Amin! 
Hallemyah” - Ifihan19:4



1.  AWA l’egbe Kerubu Serafu

    T'Oluwa fun 'ra re gbe dide

    Awa f'ohun wa ke Alleluyah

    Si Olorun Awimayehun

    Aje kan ko to lati bori Egbe yi 

    Oso kan ko to lati bori Egbe yi 

    Oluwa fun ‘ra re ni Oluto wa,

    Awa Egbe Serafu ko je f’esu laye. 

Egbe:  Eda Ie fe o, ki nwon korira

            Aiye Ie bu o, ki nwon sepe fun o 

           Bi nwon se ju yi lo nitori Jesu

           Ma wo be, ma wo be)

           Ma wo be, se 'fe Oluwa). 2ce


2.  Ayo ni ki eyi je fun yin

     Enyin ti Lusifia ti te ba 

     Oluwa ran Egbe Mimo yi

     Lati fi ase gbe nyin dide

     E mase fi aigbagbo se ‘ra nyin lese 

     Eni nla ni Jesu Olori Egbe wa, 

     Nitorina ki e f’okan nyin bale

     K'e mo p’okunkun ko bori imole ri o. 

Egbe:  Eda Ie fe o...


3.  Bi Jesibel ba mo pe beni

     Yio ii f‘on niwaju Jehu 

     Ki ba le tiro k‘o gun gege

     Tun bere pe s'alafia ni

     Eni ns‘ ota Olorun t‘o nwa' lafia 

     Anfani kil' o wa ninu aje sise

     E tari re lokiti fun aja je

     Awa Egbe Kerubu ko ni f‘esu laye. 

Egbe:  Eda Ie fe o...


4.  Ka p‘arapo sise Oluwa 

     Ninu Egbe Mimo Kerubu 

     K’a mase ro p‘enikan kere 

     J‘eniti Oluwa le lo lo 

     Ranti Alufa Eli pelu Samuel

     Modikai pelu ayaba Esta 

     Meji pere yi t‘eko fun Serafu 

     Awa Egbe Seran ko ni f’esu laye. 

Egbe:  Eda Ie fe o...


5.  Ki gbogbo aiswaju Egbe 

     Mura sile de bibo Jesu

     Irohin won ki se kekere

     Niwaju ite Baba loke

     Asaju to de be to npitan ara re

     Ki Jesu to le mo pe asiwaju ni,

     Ki y'o wo ‘nu ogo na pel‘ Oluwa 

     Awa Egbe Serafu ko je f’esu laye. 

Egbe:  Eda Ie fe o...


6.  Gbogbo enyin aje at'oso

     T’o wa ndi se Oluwa lowo 

     T'Oluwa kilo fun nyin titi

     Ti e ko fe ronupiwada

     Ranti oruko t’a ko s‘egbe ogiri 

     Mene, Mene, Tekeli Peresini

     A ti won o wo, o fuye ju gba lo 

     Awa Egbe Serafu ko ni f’esu laye.

Egbe:  Eda Ie fe o, ki nwon korira

            Aiye Ie bu o, ki nwon sepe fun o 

           Bi nwon se ju yi lo nitori Jesu

           Ma wo be, ma wo be)

           Ma wo be, se 'fe Oluwa). 2ce  Amin

English »

Update Hymn