HYMN 5

C.M.S 7, H.C. t.H.C 258 S.M. (FE 22)
"Lale loro ati losan li emi o ma 
gbadura" Ps. 55:7


1.  WA s'adura oro

     Kunle k'a gbadura; 

     Adura ni opa Kristiani,

     Lati b'Olorun rin.


2.  Losan, wole labe 

     Apat' aiyeraiye;

     Itura ojiji Re dun,

     Nigbat' orun ba mu.


3.  Je ki gbogbo ile,

     Wa gbadura l'ale

     Ki ile wa di t'Olorun,

     Ati 'bode orun.


4.  Nigbati od'oganjo

     Jek'a wi l'emi, pe 

     Mo sun, sugbon okan mi ji

     Lati ba O sona.  Amin 

English »

Update Hymn