HYMN 498

(FE 525)



1.  ALA kan ti mo la loru yi 

     Michael lo sokale wa

     Mo ri pe o fo‘tegun esu 

     Ogo ni fun Jesu li orun

Egbe:  Ka ba gbogbo Angeli sokan 

           lati korin

           To fi segun goke re orun 

           Lehin t'O ti bori esu

           Lehin t'O ti bori esu. 


2.  Kerubu pelu Serafu

     E mura ke damure nyin

     lse Oluwa l’awa nje

     Awa ki yio beru enikan

Egbe:  Ka ba gbogbo Angeli...


3.  Aki gbogb’ awon Leader wa 

     T‘o wa ba wa se Ajodun

     Ki Olorun ko mese nyin duro 

     Lati gba ‘de iye li orun.

Egbe:  Ka ba gbogbo Angeli...


4.  A ki Mose Orimolade

     Fun ‘se nla t’o se l’arin wa

     K’Olorun ko busi ise re

     Ade Ogo yio je tire.

Egbe:  Ka ba gbogbo Angeli sokan 

           lati korin

           To fi segun goke re orun 

           Lehin t'O ti bori esu

           Lehin t'O ti bori esu.  Amin

English »

Update Hymn