HYMN 497

(FE 524) 
Tune: Oluwa Olorun gba wa



1.  EGBE Aladura mura

     Lati pade Kerubu
 
    Jesu lo pe nyin lo yan nyin 

    On lo d’Egbe yi sile

    O si pe gbogbo aiye

    Lati w’oko ‘gbala yi

    Jesu mu wa de ‘te ogo 

    B’ojo wa ti nkoja lo.

Egbe:  Ojo nlo, Ojo nlo. 2ce

           Ise po t'awa yio se

           B’ ojo wa ti nkoja Io.


2.  Egbe Serafu d’amure 

     Lati pade Kerubu

     E ma je k’amure nyin tu 

     Lati pade Kerubu

     Gbe ida ‘segun soke

     Iye s’Olorun Daniel 

     Alleluya Jesu mbo

     B’ojo wa ti nkoja lo 

Egbe:  Ojo nlo, Ojo nlo...


3.  Olorun Metalokan wa 

     Lati gbo adura mi 

     Jesu Olugbala mi wa 

     Lati gb’ebo ope mi 

     Emi Mimo sokale

     F’ore ofe ba wa gbe

     Ise po t’awa o se

     B‘ojo wa ti nkoja lo 

Egbe:  Ojo nlo, Ojo nlo...


4.  F'okan fe so gbogbo wa po 

     B'ojo wa ti nkoja lo

     Kokan la o fa won s'agbo wa, 

     B’ojo wa ti nkoja lo

     Sugbon ‘eso ti a gbin 

     L‘osan at‘oru yio hu 

     Gb’awon to subu dide

     B’ojo wa ti nkoja lo.
     
Egbe:  Ojo nlo, Ojo nlo. 2ce

           Ise po t'awa yio se

           B’ ojo wa ti nkoja Io.  Amin

English »

Update Hymn